Ki irun ni iduro, ti oo ba wa ni ikapa, yaa ki i ni ijokoo, ti oo ba tun wa ni ikapa, ki i ni ifẹgbẹlelẹ
Lati ọdọ ‘Imrān ọmọ Husoyn – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Aisan jẹ̀díjẹ̀dí mu mi, nigba naa ni mo wa bi Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – leere nipa irun, ni o wa sọ pe: «Ki irun ni iduro, ti oo ba wa ni ikapa, yaa ki i ni ijokoo, ti oo ba tun wa ni ikapa, ki i ni ifẹgbẹlelẹ».
Bukhaariy gba a wa
Àlàyé
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye wipe dajudaju ipilẹ ninu irun ni iduro, ayaafi ni igba ti ko ba si ikapa, nigba naa yio ki i ni ẹnití o jokoo, ti ko ba tun ni ikapa kiki irun ni ẹni ti o jokoo, o le ki i ni ifẹgbẹlelẹ.
Hadeeth benefits
Wọn o le yọnda irun lopin igba ti laakaye ba ṣi wa, nigba naa kikuro ni ipo kan si ipo miran a maa ṣẹlẹ ni ibamu si ikapa.
Irọrun Isilaamu n bẹ nibi pe ẹrú yio maa ṣe eyikeyii ti o ba ti rọ ọ lọrun ninu ijọsin.
Share
Use the QR code to easily share the message of Islam with others