“Irun kan ti a ba ki ni mọsalasi mi yii loore ju ẹgbẹ̀rún irun lọ ti a ki ni ibi ti o yatọ si i afi irun ti a ki ni mọsalasi abeewọ”
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Irun kan ti a ba ki ni mọsalasi mi yii loore ju ẹgbẹ̀rún irun lọ ti a ki ni ibi ti o yatọ si i afi irun ti a ki ni mọsalasi abeewọ”.
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Àlàyé
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé ọla ti o n bẹ fun irun ti a ki ni mọsalasi rẹ, pe o lọla ni ẹsan ju ẹgbẹrun irun ti a ki lọ ni ibi ti o yatọ si i ninu awọn mọsalasi aye, afi irun ti a ba ki ni mọsalasi ọwọ ni Makkah, oun lọla ju irun ti a ki ni mọsalasi rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lọ.
Hadeeth benefits
Adipele ẹsan fun irun ti a ba ki ni mọsalasi abeewọ, ati ni mọsalasi ti Anabi.
Irun ti a ba ki ni mọsalasi abeewọ loore ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún irun ti a ki ni eyi ti o yatọ si i ninu awọn mọsalasi lọ.
Share
Use the QR code to easily share the message of Islam with others