- Ar-Rọhim ni àwọn mọlẹbi ni igun ti bàbá ati iya, bi o ba ṣe sunmọ si naa ni o ṣe ni ẹtọ láti da a pọ̀ tó.
- Ẹsan maa wa latara iran iṣẹ ni, ẹni tí ó bá da ẹbí rẹ pọ pẹ̀lú dáadáa, Ọlọhun maa da a pọ̀ nibi ọjọ́-orí rẹ ati arisiki rẹ.
- Dida ẹbí pọ jẹ okùnfà gbígbòòrò arisiki ati ẹmi gígùn, bi o tilẹ̀ jẹ́ pé àsìkò ti èèyàn maa lò laye ati arisiki ti ni gbèdéke, ṣùgbọ́n o tun le jẹ ìbùkún nibi arisiki ati ọjọ́-orí, o maa wa fi ìgbésí ayé rẹ ṣe nǹkan ti o maa pọ ti o si maa ṣe àǹfààní ju nǹkan ti ẹlòmíràn maa ṣe lọ, àwọn kan sọ pé alekun arisiki ati ọjọ́-orí naa maa jẹ alekun gidi. Ọlọhun ni O ni imọ julọ.