- Okunfa ṣiṣe ọtí ni eewọ ni pipani, nitori naa gbogbo nkan ti o ba ti n pani, iran yòówù ki o jẹ, èèwọ̀ ni.
- Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe ọtí ni eewọ latari nkan ti o ko sinu ni awọn inira ati awọn ibajẹ ti o tobi.
- Mimu ọtí ninu al-jannah ninu pipe adun ati idẹkun ni o wa.
- Ẹni ti ko ba ko ẹmi rẹ ro nibi ọti mimu ni ayé, Ọlọhun yoo ṣe mimu rẹ ni eewọ fun un ninu al-jannah, nítorí pé igba ti wọn ba fi wínkà ni wọn fi n san an.
- Ṣiṣenilojukokoro lori yiyara tuuba kuro nibi ẹṣẹ ṣaaju iku.