- Siso okun-ẹbi tí ó wà ní ibamu pẹlu Sharia ni pé kí o sopọ mọ awọn tí wọ́n bá já ọ danu kuro laarin wọn, ki o sì ṣamojukuro fun awọn ti wọ́n bá ṣabosi sí ọ, ki o sì fún awọn ti wọ́n bá ṣahun si ọ, kii ṣe pé ki o sopọ pẹlu sísẹ̀san iru nkan ti wọ́n ṣe si ọ.
- Siso okun-ẹbi ni pé kí o mu de ọdọ wọn nkan tó bá rọ ọ lọrun ninu oore, bii owo, adura, pipaṣẹ nkan dáadáa, kikọ nkan aburu, ati iru bẹẹ, kí o sì ti aburu dànù fun wọn bí ó bá ti rọrun fun ọ.