- Didara ikọni ni ẹ̀kọ́ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- bi o ṣe n ju àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn silẹ nípasẹ̀ ìbéèrè.
- Didara ẹkọ àwọn saabe pẹ̀lú Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, nígbà tí wọ́n sọ pe: Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni wọn mọ̀ julọ.
- Ki ẹni tí wọ́n ba bi ni ibeere nipa nǹkan ti kò mọ̀ sọ pe: Ọlọhun ni O ni imọ julọ.
- Sharia ṣọ àwùjọ pẹlu ṣiṣọ àwọn ẹ̀tọ́ àti ijẹ ọmọ-iya laarin wọn.
- Eewọ ni ọrọ-ẹyin ayafi ni àwọn iṣesi kan fun àǹfààní; ninu rẹ ni: Dida àbòsí padà, nibi ti ẹni tí wọ́n ṣe abosi si ti maa dárúkọ ẹni ti o ṣe abosi si i lọdọ ẹni ti o ba le ba a gba ẹtọ rẹ, o maa sọ pé: Lagbaja ṣe àbòsí fun mi, tabi o ṣe bayii fun mi, nínú rẹ̀ ni: Ìjíròrò nipa ọrọ ìgbéyàwó, tabi jijọ da nǹkan papọ, tabi mimu ilé ti ara ẹni, àti ohun ti o jọ ìyẹn.