- Sisan abẹtẹlẹ jẹ eewọ, ati gbigba a, ati ṣiṣe alagata nibẹ, ati ṣiṣe ikunlọwọ lori rẹ; latari nkan ti o wa ninu rẹ ni ikunlọwọ lori ibajẹ.
- Abẹtẹlẹ wa ninu awọn ẹṣẹ ti o tobi; torí pé dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣẹbi le ẹni ti n gba a ati ẹni ti n san an.
- Ọran nla ni abẹtẹlẹ jẹ ni agbegbe idajọ ati ofin, ẹṣẹ ti o ni agbara si tun ni; latari nkan ti o wa ninu rẹ ni abosi ati ṣiṣe idajọ pẹlu nkan ti o yatọ si nkan ti Ọlọhun sọkalẹ.