- Ìní-ẹ̀tọ́ si ìyà ẹni ti o ba pinnu láti da ẹ̀ṣẹ̀ nínú ọkàn rẹ ti o si ṣe àwọn okùnfà rẹ tààrà.
- Ikilọ ti o lágbára kúrò nibi ki awọn Mùsùlùmí maa ba ara wọn ja, ati àdéhùn ìyà iná lori ẹ.
- Ìjà láàárín àwọn Musulumi pẹlu ẹ̀tọ́ kò kó sínú adehun ìyà naa, gẹgẹ bii bíbá àwọn ti o kọjá ẹnu-ala jà ati awọn obilẹjẹ.
- Ẹni ti o ba da ẹṣẹ ńlá ko nii di Kèfèrí pẹlu ọ̀wọ́ pé ó kàn dá ẹṣẹ naa; torí pé Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe àwọn ti wọn n ba ara wọn jà ni Musulumi.
- Ti Musulumi meji ba pade ara wọn pẹ̀lú èyíkéyìí nǹkan ti wọn le fi pa èèyàn, ti ọkan ninu wọn wa pa ikeji, ẹni ti o pa èèyàn ati ẹni tí wọ́n pa maa wọ ina, wọn kan dárúkọ idà ninu hadiisi naa lati fi ṣe àpèjúwe ni.