- Wiwa iṣọra ìjọsìn ni, oun naa ni eyi ti o ba jẹ pẹlu Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, tabi awọn orúkọ Rẹ ati awọn ìròyìn Rẹ.
- Ìní-ẹ̀tọ́ wiwa iṣọra pẹlu ọrọ Ọlọhun; torí pé o jẹ ọkan ninu awọn ìròyìn Rẹ, yatọ si ìwá-ìṣọ́ra pẹlu èyíkéyìí ẹ̀dá, ẹbọ ni ìyẹn.
- Ọla ti n bẹ fun adua yii ati alubarika rẹ.
- Wiwa ààbò pẹ̀lú àwọn iranti Ọlọhun jẹ okùnfà láti ṣọ́ ẹrú kúrò nibi aburú.
- Bíba ìwá-ìṣọ́ra pẹ̀lú ohun ti o yatọ si Ọlọhun jẹ́, bii alujannu, ati awọn opidan, ati awọn ẹni èké, ati awọn mìíràn.
- Adua yii jẹ nnkan ti o ba sharia mu fun ẹni tí ó ba sọ̀kalẹ̀ si ààyè kan ni ilé tabi ni ìrìn-àjò.