Eyi tó lọ́lá jùlọ ninu awọn iranti Ọlọhun ni gbolohun: LAA ILAAHA ILLALLOOH, eyi tó sì lọ́lá jùlọ ninu awọn adura ni gbolohun: ALHAMDULILLAH
Lati ọdọ Jabir - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Mo gbọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí n sọ pé: "Eyi tó lọ́lá jùlọ ninu awọn iranti Ọlọhun ni gbolohun: LAA ILAAHA ILLALLOOH, eyi tó sì lọ́lá jùlọ ninu awọn adura ni gbolohun: ALHAMDULILLAH".
Tirmiziy ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa ninu al-Kubrọ, ati Ibnu Maajah
Àlàyé
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ fún wa pé iranti Ọlọhun tó lọ́lá jùlọ ni: "LAA ILAAHA ILLALLOOH" itumọ rẹ̀ ni pé kò sí nkankan tí a gbọdọ̀ jọsin fun pẹlu ododo ayafi Ọlọhun Allah, ati pé adura tó lọ́lá jùlọ ni ALHAMDULILLAH; iyẹn ni pé a n fi rinlẹ̀ pé dajudaju Allahu ni Oluṣedẹra fún wa, Oun ni O sì lẹtọọ si iroyin tó pé, tó sì dara julọ.
Hadeeth benefits
Ìgbani ní ìyànjú lati maa ṣe iranti Ọlọhun ni pupọ pẹlu gbolohun iṣe Ọlọhun lọ́kan, ati lati maa gbadura pẹlu gbolohun ọpẹ́.
Share
Use the QR code to easily share the message of Islam with others