- Fífi ìṣìpẹ̀ rinlẹ̀ fun Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni ọjọ ikẹyin, ati pé ìṣìpẹ̀ naa ko nii sí fun ẹnikankan ayafi awọn tí wọ́n ṣe Ọlọhun lọ́kan ṣoṣo.
- Ìṣìpẹ̀ rẹ̀ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - oun ni ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ si Ọlọhun Ọba fun awọn tí ó yẹ kí wọ́n wọ ina Jahannama ninu awọn oluṣọlọhun lọ́kan pé kí wọ́n má wọ inu rẹ̀, ati pé kí awọn tí ó ti wà ninu ina lè jáde kuro ninu rẹ̀.
- Ọlá tí n bẹ fun gbolohun iṣọlọhun lọ́kan tó jẹ́ ododo mímọ́ fun Ọlọhun Ọba, ati títóbi orípa gbolohun naa.
- Gbolohun iṣọlọhun lọ́kan yoo maa di òtítọ́ pẹlu mímọ itumọ rẹ̀, ati fífi nǹkan ti o n bèèrè fun ṣiṣé ṣe.
- Ọlá tí n bẹ fún Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ati ìtaraṣàṣà rẹ̀ sí ìmọ̀.