- Sisọ LAA ILAAHA ILLALLOHU, ati ṣíṣe aigbagbọ pẹlu gbogbo nnkan ti wọn n jọsin fun yatọ si Ọlọhun, jẹ majẹmu nibi wiwọ inu Isilaamu.
- Itumọ (LAA ILAAHA ILLALLOHU) ni ṣíṣe aigbagbọ pẹlu gbogbo nnkan ti wọn n jọsin fun yatọ si Ọlọhun ninu awọn oosa ati awọn sàréè ati nnkan ti o yatọ si wọn, ati mimu U- mimọ ni fun Un- ni Ọkan ṣoṣo pẹlu ijọsin.
- Ẹni ti o ba mu ìmú-Ọlọ́hun-lọ́kan wa ti o si dunni mọ awọn ofin rẹ ni ti gbangba, ikoraro kuro fun un jẹ dandan titi ti nnkan ti o yatọ si ìyẹn yoo fi han lati ọdọ rẹ.
- Jijẹ eewọ dukia Musulumi ati ẹjẹ rẹ ati iyì rẹ afi pẹlu ẹtọ.
- Idajọ ni aye wa lori nǹkan ti o ba hàn, o si wa lori awọn aniyan ati awọn erongba ni ọrun.