- Àwọn ijọsin wọn mọ wọn pa lori nnkan ti o ba wa ninu Kuraani ati sunnah, a ko lee jọsin fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- afi pẹlu nnkan ti o ba ṣe lofin, ti ko ki n ṣe pẹlu awọn adadaalẹ ati awọn nnkan tuntun.
- Ẹsin ko ki n ṣe pẹlu irori ati riri i pe nnkan dáa, bi ko ṣe pe pẹlu itẹle ojiṣẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni.
- Hadiisi yii jẹ ẹri lori pipe ẹsin.
- Adadaalẹ ni gbogbo nnkan ti wọn da a lẹ ninu ẹsin ti ko si laye Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati laye awọn saabe rẹ ninu adisọkan tabi ọrọ tabi iṣẹ.
- Hadiisi yii jẹ ipilẹ kan ninu awọn ipilẹ Isilaamu, o da gẹgẹ bii òṣùwọ̀n fun awọn iṣẹ, gẹgẹ bi o ṣe jẹ́ pé gbogbo iṣẹ ti wọn ko ba fi wa oju rere Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, ko si ẹsan kan fun ẹni ti o ṣe e nibẹ, gẹgẹ bẹẹ naa ni pe gbogbo iṣẹ ti ko ba ti ba nnkan ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- mu wa mu, wọn maa da a pada fun ẹni ti o ba ṣe e.
- Àwọn adadaalẹ ti a kọ kuro nibẹ ni gbogbo nnkan ti o ba ti wa ninu awọn alamọri ẹsin ti ko ki n ṣe ti aye.