- Alaye iwọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti O ṣe e ni dandan lori awọn ẹrusin Rẹ, oun ni ki wọn maa jọsin fun Un, ki wọn si ma da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ.
- Alaye iwọ awọn ẹrusin lori Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti O ṣe e ni dandan fun ara Rẹ ni ti ọla lati ọdọ Rẹ ati idẹra, oun ni ki O mu wọn wọ alujanna, ki o si ma fi iya jẹ wọn.
- Iro idunnu ti o tobi n bẹ nibẹ fun awọn ti wọn mu U ni Ọkan ti wọn ko da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ pe ìkángun wọn ni wiwọ alujanna.
- Mu’aadh sọ hadisi yii ṣíwájú iku rẹ; ni ti ipaya kiko si inu ẹṣẹ fifi imọ pamọ.
- Akiyesi lori aima fọn apakan awọn hadisi ka lọdọ awọn eniyan kan ni ti ibẹru lori ẹni ti ko ni imọ nipa ìtumọ̀ rẹ; ìyẹn nibi nnkan ti ko si iṣẹ lábẹ́ rẹ tabi ìjìyà kan ninu awọn ìjìyà Sharia.
- Àwọn ẹlẹṣẹ nínú awọn ti wọn mu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo wa lábẹ́ fifẹ Ọlọhun, ti O ba fẹ yoo fi iya jẹ wọn ti O ba si fẹ yoo fori jin wọn, lẹyin naa ìkángun wọn maa jẹ alujanna.