- Itumọ ijẹrii pé kò sí ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah ni pé ki a ṣe Ọlọhun lọ́kan ṣoṣo nibi ijọsin wa, kí a sì gbé ijọsin ohun tó yatọ si I jù sílẹ̀.
- Itumọ ijẹrii pé Anabi Muhammad Ojiṣẹ Ọlọhun ní ń ṣe ni pé kí a ní igbagbọ si i, kí a sì ní igbagbọ sí ohun tí ó mú wá, kí a sì pè é lódodo, ati pé oun ni ikẹhin awọn Ojiṣẹ Ọlọhun sí gbogbo ènìyàn.
- Bí a ṣe maa bá oní mímọ̀ sọ̀rọ̀ ati ẹniti ó ní ìrújú, ó yatọ si bi a ṣe maa bá alaimọkan sọrọ; nítorí náà ni Anabi ṣe ṣalaye fún Muaz pé: “Ìwọ yóò lọ bá àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ oni-tira sánmọ̀”.
- Pàtàkì kí musulumi jẹ́ onimimọ nipa ẹsin rẹ̀; kí ó lè móríbọ́ kuro nibi ìrújú awọn onírújú, látara wíwá ìmọ̀.
- Bíbàjẹ́ ẹsin awọn Yahudi ati Nasara lẹyin tí Ọlọhun ti gbé Anabi Muhammad dìde - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ati pé wọn kò sí ninu awọn ti yoo là ní ọjọ igbende ayafi tí wọ́n bá wọ inu ẹsin Islam, kí wọ́n sì gba Anabi gbọ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a.