- Jijuralọ awọn ẹṣẹ nibi títóbi, gẹgẹ bi awọn iṣẹ oloore naa ṣe maa n ju ara wọn lọ nibi ọla.
- Eyi ti o tobi julọ ninu awọn ẹṣẹ ni: Imu orogun pọ mọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, lẹyin naa pipa ọmọ nitori ipaya ki o maa jẹun pẹlu rẹ, lẹyin naa ki o ṣe ṣina pẹlu iyawo ara adugbo rẹ.
- Arisiki wa lọwọ Ọlọhun, Ọlọhun- mimọ ni fun Un- si ti mu ìpèsè arisiki awọn ẹda da wa lójú.
- Titobi iwọ ara adugbo, ati pe dajudaju fifi suta kan an tobi ni ti ẹṣẹ ju fifi suta kan ẹni ti o yàtọ̀ si i lọ.
- Aṣẹda ni Ẹni ti O lẹtọọ si ijọsin ni Oun nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un.