- kíkọ̀ fun wa kuro nibi kí a má maa jọsin fun Ọlọhun Ọba ninu awọn ile wa.
- kíkọ̀ fun wa kuro nibi ìrìn-àjò lati lọ ṣabẹwo saare Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nítorí pé ó paṣẹ fun wa pe ki a maa ṣe asalatu fun oun, ó sì sọ pe yoo kan oun lara, ṣugbọn a lè ṣe irin-ajo lati lọ ṣabẹwo mọṣalaṣi Anabi kí a sì kirun ninu rẹ̀.
- Èèwọ̀ ni ki a sọ abẹwo saare Anabi di ọdun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nipa pípàárà abẹwo saare rẹ̀ ni ọna kan ati asiko kan pato, bakan naa ni ṣiṣe abẹwo gbogbo saare.
- Apọnle ti n bẹ fun Anabi lọdọ Oluwa rẹ̀ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pẹlu ṣíṣe ìtọrọ ìkẹ́ ati ìgẹ̀ fun Anabi lófin ní gbogbo ìgbà ati àyè.
- Níwọ̀n ìgbà tí ìkọ̀fúnni kuro nibi kíkírun nibi awọn saare ti fẹsẹ rinlẹ lọdọ awọn sahaaba; idi niyi ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - fí ń kọ̀ fun wa pé a ò gbọdọ̀ ṣe awọn ile wa gẹgẹ bii itẹ́ saare tí wọn ò kí ń kírun nibẹ.