- Ìgbani níyànjú lati maa kéde òfin sharia Ọlọ́hun, àti pé ènìyàn gbọ́dọ̀ kéde ohun tí ó bá há sórí, tí ó sì gbágbọ̀yéé rẹ̀, koda bó jẹ́ pé díẹ̀ ni.
- Ọ̀ranyàn ni wíwá ìmọ̀ ofin sharia; kí a lè jọsin fun Ọlọhun ní ìrọ̀rùn, kí a sì lè kede sharia Rẹ̀ ní àwòrán tó lalaafia.
- Ọ̀ranyàn ni kí a ri i dájú pé èyíkéyìí hadiisi ní alaafia siwaju kí a tó kede rẹ̀, nitori kí a má baa kó sí inu ìlérí tó lekoko yii.
- Ìgbani níyanju lati maa sọ ododo ati ìmáa ṣọra nibi ọrọ sisọ, kí a má baa kó sinu irọ́, paapaa julọ ninu ofin Ọlọhun Ọba.