- O tọ ki èèyàn máa ko airoju pẹlu nkan ti o pataki julọ ti a bukaata si i, ati gbigbe nkan ti a ko bukaata si lẹsẹkẹsẹ ju silẹ, ki a sì ma maa ko airoju pẹlu bibeere nipa nkan ti ko i tii ṣẹlẹ.
- Jijẹ eewọ ibeere ti o ṣeeṣe ki o fa titakoko awọn ọ̀rọ̀ (ibeere), ati sisi ilẹkun awọn iruju sílẹ̀, èyí ti o le fa ọpọ ìyapa.
- Ipaṣẹ pẹlu gbigbe awọn nkan ti wọn kọ silẹ; torí pé ko si inira nibi gbigbe e silẹ, tori naa ni kikọ fi jẹ nkan ti o kari.
- Ipanilaṣẹ pẹlu ṣiṣe nkan ti wọn pàṣẹ rẹ bi agbara ba ṣe mọ; torí pé inira le wa nibẹ nigba miran tabi ki o kagara lati ṣe e; fun idi eyi ni aṣẹ rẹ fi wa lori bi ikapa ba ṣe mọ.
- Kikọ kuro n'ibi apọju ibeere, awọn olumọ ti pin ibeere si meji: Ikinni: Eyi ti o ba wa ni ọna ikọnilẹkọọ nipa nkan ti wọn bukaata si ninu alamọri ẹsin, eleyii wọn pàṣẹ rẹ, abẹ rẹ si ni gbogbo ibeere awọn saabe ko si, ikeji: Eyiti o wa ni ọ̀nà ifitipa béèrè , eleyii ni wọn kọ kuro nibẹ.
- Ṣiṣe ikilọ fun ijọ yii (ijo Anabi Muhammad) kuro nibi yiyapa Anabi rẹ, gẹgẹ bi o ṣe ṣẹlẹ si awọn ijọ ti o ṣaaju rẹ.
- Apọju ibeere nipa nkan ti a ko bukaata si ati ìyapa awọn Anabi okunfa iparun ni, agaga julọ nibi awọn alamọri ti eeyan o lee de ibẹ, gẹgẹ bii: Awọn alamọri ikọkọ ti ko si ẹni ti o mọ ọn ayaafi Ọlọhun, ati awọn iṣesi ọjọ igbedide.
- Kikọ kuro nibi bibeere nípa àwọn ọ̀rọ̀ ti o le, Al-Awzā‘i sọ pe: Dajudaju ti Ọlọhun ba gbero lati jẹ ki ẹrú Rẹ pàdánù ibukun imọ, yoo fi awọn ọrọ tii muni ko sínú àṣìṣe si ori ahọn rẹ, mo si ti ri wọn ni ẹni ti o fi n kere julọ ni imọ, Ibnu Wahb naa tun sọ pe: Mo gbọ ti Mālik n sọ pe: Iyanjija nibi mimọ maa n pa imọlẹ mimọ ninu ọkan eeyan.