- Gbigbe sunnah tobi gẹgẹ bi wọn ṣe maa n gbe Kuraani tobi ti wọn si maa n ṣe iṣẹ́ pẹlu rẹ.
- Itẹle Òjíṣẹ́ ni itẹle ti Ọlọhun, iyapa rẹ naa si jẹ ìyapa Ọlọhun ti ọla Rẹ ga.
- Ẹri to fẹsẹrinlẹ ni Sunnah ati fifesi fun awọn ti wọn kọ Sunnah tabi ti wọn tako o.
- Ẹni ti o ba gunri kuro nibi sunnah ti o so pe Kuraani nìkan ti to, o ti gunri kuro nibi mejeeji lapapọ, o si tun jẹ opurọ nibi apemọra itẹle Kuraani rẹ.
- Ninu awọn ẹri ijẹ-anabi rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni àwọn nǹkan tí ó sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ ni ọjọ́ iwájú, ti o si ṣẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wí.