- Iṣọnilara kuro nibi titayọ aala ofin sharia nibi ẹyìn; nitori pe ó máa n ja si ẹbọ ni.
- Ohun ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n kilọ fun wa nipa rẹ̀, ó ti ṣẹlẹ ninu ijọ yii, nitori awọn ẹgbẹ kan ti tayọ aala lara Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - awọn ẹgbẹ kan sì tayọ aala lara awọn ara ile Anabi, awọn ẹgbẹ kan tún tayọ aala lara awọn wòlíì Ọlọhun, gbogbo wọn bá kó sinu ẹbọ.
- Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - royin ara rẹ̀ pé ẹru Ọlọhun ni oun; nitori kí ó lè fi hàn pé dajudaju ẹru ti Allah ń rè ni oun, nitori naa kò lẹtọọ ki a dari nkankan ninu awọn ìròyìn ẹ̀ṣà Oluwa si ọdọ rẹ̀.
- Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - royin ara rẹ̀ pé ojiṣẹ Ọlọhun ni oun; nitori kí ó lè fi hàn pé dajudaju ojiṣẹ kan lati ọdọ Ọlọhun ni oun, nitori naa ọranyan ni ki a pe e lódodo ki a si tẹle e.