- Kikọ kuro nibi mimu awọn saare awọn Anabi ati awọn ẹni rere ni mọsalasi ti wọn maa kirun nibẹ fun Ọlọhun, nitori pe ìyẹn jẹ atẹgun lọ sibi ẹbọ.
- Ini akolekan ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati amojuto rẹ gan si imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo ati ibẹru rẹ fun bibabara awọn saare; nitori ìyẹn maa ja si ẹbọ.
- Ṣiṣe lẹtọọ ṣiṣẹbi le awọn Juu ati Nasara ati ẹni ti o ba ṣe bii iṣe wọn ninu mimọ nnkan sori awọn saare ati mimu wọn ni mọsalasi.
- Mimọ nnkan sori awọn saare wa ninu awọn oju ọna Juu ati Nasara, kikọ kuro nibi fifi ara wé wọn si n bẹ ninu hadiisi náà.
- Kiki irun nibẹ tabi si i lara n bẹ ninu mimu awọn saare ni mọsalasi, koda ki wọn ma kọ mọsalasi.