- Itẹle ojiṣẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ninu itẹle Ọlọhun, yiyapa rẹ naa si wa ninu ìyapa Ọlọhun.
- Itẹle Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa sọ alujanna di dandan, yiyapa rẹ maa sọ iná di dandan.
- Ìró ìdùnnú fun awọn olutẹle ninu ijọ yii pe gbogbo wọn ni wọ́n maa wọ alujanna ayafi ẹni tí ó bá yapa Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ.
- Aanu Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fun ìjọ rẹ, ati ojúkòkòrò rẹ lati fi wọn mọ̀nà.