- Títayọ aala ofin sharia nibi saare awọn Anabi ati awọn ẹni rere yoo jẹ ki awọn eniyan maa jọsin fún wọn dipo Ọlọhun, nitori naa, ọranyan ni kí a wá ìṣọra kuro nibi awọn ọna ẹbọ.
- Kò tọ́ láti lọ síbi saare nitori gbígbé títóbi fun un ati ṣiṣe ìjọsìn níbẹ̀, bó ti lè wù kí ẹni tí ó wà ninu saare naa sunmọ Ọlọhun Ọba tó.
- Eewọ ni kíkọ́ mọṣalaṣi sori àwọn saare.
- Eewọ ni kí a máa kírun níbi saare, kódà bí wọn ò bá kọ́ mọṣalaṣi, ayafi kíkí ìrun sí òkú tí wọn ò tíì kirun sí lara.