- Titobi ati ọla ti n bẹ fun imọ sharia ati kikọ ọ, ati ṣisẹnilojukokoro lori ẹ.
- Diduro ti òdodo gbọdọ wa ninu ijọ yii, ti àwọn ikọ̀ kan ba ti pa á tì, àwọn ikọ̀ mìíràn maa dúró tì í.
- Níní agbọye ninu ẹsin wa ninu pe Ọlọhun fẹ oore fun ẹrú rẹ.
- Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n fúnni pẹ̀lú àṣẹ Ọlọhun ati fífẹ́ Rẹ, ati pe ko ni ikapa nǹkan kan.