- Ọla ti n bẹ fun imaa dupẹ lori idunnu ati ṣiṣe suuru lori inira, ati pe ẹni ti o ba ṣe ìyẹn yio ri ẹsan aye ati ọjọ ikẹyin, ati pe ẹni ti ko ba dupẹ lori idẹra, ti ko sì ṣe suuru lori adanwo, ẹsan ti bọ fun un, ti ẹṣẹ si ti wa fun un.
- Ọla ti n bẹ fun igbagbọ, ati pe dajudaju gbigba ẹsan nibi gbogbo ìṣesí ko si fun ẹnikankan ayaafi awọn onigbagbọ.
- Idupẹ nigba idunnu ati ṣiṣe suuru lori adanwo ninu awọn iwa awọn olugbagbọ ni o wa.
- Nini igbagbọ si akọsilẹ Ọlọhun ati kadara Rẹ yio maa jẹ ki mumini o maa yọnu tan yan-an-yan lori gbogbo ìṣesí rẹ, yatọ si ẹni ti kii ṣe mumini ti yio maa binu ni gbogbo igba nígbà tí inira ba ṣẹlẹ si i, ti o ba tun ri idẹra lati ọdọ Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn yio ko airoju pẹlu rẹ kuro nibi itẹle aṣẹ Ọlọhun, ka mai tii sọ lilo o sibi ìyapa Ọlọhun.