- Alaye ọla ti o n bẹ fun Ọlọhun lori awọn ẹru Rẹ ti wọn jẹ olugbagbọ ati ikẹ Rẹ pẹlu wọn pẹlu iforijin awọn ẹṣẹ wọn pẹlu eyi ti o kere julọ ninu inira ti o ba ṣẹlẹ̀ si wọn.
- O tọ fun Musulumi lati maa reti ẹsan nnkan ti o ṣẹlẹ̀ si i lọdọ Ọlọhun, ki o si ṣe suuru lori gbogbo nnkan kekere ati ńlá, ki agbega ninu awọn ipo le jẹ tirẹ ati ipa awọn aburu rẹ.