- Alaye ilana rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi sinsin ati iwo awokọṣe rẹ nibi ìyẹn.
- Ṣíṣe gbigbe aṣọ tabi inuju ati nnkan ti o jọ ọ sori ẹnu rẹ ni nnkan ti a fẹ ati sori imu rẹ ki nnkan kan ti o le ko suta ba alabajokoo rẹ ma baa jade lati ọdọ rẹ nigba ti o ba sin.
- Irẹ ohun sinsin silẹ jẹ nnkan ti a fẹ, ó wa ninu pipe ẹkọ, ninu awọn iwa ti o daa si ni.