“Dajudaju Ọlọhun maa n fẹ́ lati mu awọn ofin idẹkun Rẹ wa, gẹgẹ bi O ṣe nífẹ̀ẹ́ lati mu awọn eyi ti o jẹ dandan wa”
Lati ọdọ Ibnu Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Ojisẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dajudaju Ọlọhun maa n fẹ́ lati mu awọn ofin idẹkun Rẹ wa, gẹgẹ bi O ṣe nífẹ̀ẹ́ lati mu awọn eyi ti o jẹ dandan wa”.
Ibnu Hibbaan ni o gba a wa
Àlàyé
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: Dajudaju Ọlọhun maa n nífẹ̀ẹ́ sí mímú awọn ofin idẹkun Rẹ ti O ṣe wọn lofin wa, ninu awọn nnkan ti O ṣe wọn ni fifuyẹ nibi awọn idajọ ati ijọsin, ati ṣíṣe irọrun nibẹ fun awọn ẹni ti a la iwọ Ọlọhun bọ lọrun fun idi kan- gẹgẹ bii dindin irun ku ati dida a pọ ni ori irin ajo-, Gẹgẹ bi O ṣe nífẹ̀ẹ́ si mimu awọn ofin ti wọn jẹ dandan wa, ninu awọn alamọri ti wọn jẹ dandan; nitori pe aṣẹ Ọlọhun nibi awọn ìdẹkùn ati awọn nnkan ti wọn jẹ dandan jẹ ọ̀kan.
Hadeeth benefits
Ikẹ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- lori awọn ẹru Rẹ, ati pe Ọlọhun- mimọ ni fun Un- nífẹ̀ẹ́ si mimu nnkan ti o ba ṣe lofin wa ninu awọn idẹkun.
Pipe ofin sharia yii, ati gbigbe ìdààmú rẹ kuro fun Musulumi.
Share
Use the QR code to easily share the message of Islam with others