“Ẹni tí Ọlọhun ba fẹ oore fún, O maa fi àdánwò kàn án”
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni tí Ọlọhun ba fẹ oore fún, O maa fi àdánwò kàn án”.
Bukhaariy gba a wa
Àlàyé
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ti Ọlọhun ba fẹ oore fun ọkan ninu awọn ẹru Rẹ ti wọn jẹ mumini, o maa fi àdánwò kan wọn ninu ẹmi wọn ati dúkìá wọn ati ẹbi wọn, torí ìsádi Ọlọhun ti o maa ṣẹlẹ̀ si mumini ninu ẹ pẹ̀lú adua ati pipa awọn iṣẹ buruku rẹ́ ati agbega ní ipò.
Hadeeth benefits
Onigbagbọ òdodo maa ri oríṣiríṣi àdánwò.
Àdánwò le jẹ àmì ìfẹ́ Ọlọhun fun ẹrú Rẹ, titi ti yoo fi gbe ipò rẹ ga, ti o si maa pa àṣìṣe rẹ̀ rẹ́.
Ṣiṣenilojukokoro lori suuru nigba àdánwò, ki èèyàn má sì ba ara jẹ.
Share
Use the QR code to easily share the message of Islam with others