Tí ẹrú Ọlọhun kan bá ṣàìsàn tabi ó rin irin-ajo, wọn yoo kọ laada silẹ fun un fún iṣẹ tí n ṣe nigba tí ó wà nílé tó sì lalaafia
Lati ọdọ Abu Musa Al-ash’ari - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé: "Tí ẹrú Ọlọhun kan bá ṣàìsàn tabi ó rin irin-ajo, wọn yoo kọ laada silẹ fun un fún iṣẹ tí n ṣe nigba tí ó wà nílé tó sì lalaafia".
Bukhaariy gba a wa
Àlàyé
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọrọ nipa oore-ọfẹ Ọlọhun ati ikẹ Rẹ̀ lori musulumi, tí ó fi jẹ́ pé tí ó bá wà ninu àṣà musulumi pé ó máa ń ṣiṣẹ́ rere kan ní ẹni tó ní alaafia, tí kò sì rinrin ajo, musulumi naa wáá ní awawi kan latara pé ó ṣaisan, kò wá lè ṣe iṣẹ rere naa, tabi pé ó ṣairoju pẹlu irin-ajo, tabi èyíkéyìí ninu awọn awawi; dajudaju wọn maa kọ laada iṣẹ rere naa silẹ fun un ní pípé, bí ẹni pé ó ṣiṣẹ naa ni awọn asiko tó ni alaafia, tí kò sì wà ní irin-ajo.
Hadeeth benefits
Gbígbòòrò oore-ọfẹ Ọlọhun lori awọn ẹru Rẹ̀.
Rírọni lati maa gbiyanju ṣe awọn ijọsin fun Ọlọhun, kí a sì maa lo awọn asiko wa dáadáa nigba tí a bá wà ní alaafia, tí a sì ráyè.
Share
Use the QR code to easily share the message of Islam with others