Àlàyé
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n gba ẹgbawa láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀ pe ti ẹrú ba da ẹṣẹ kan, ti o wa sọ pé: Irẹ Ọlọhun, fi ori ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o wa mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti yoo waa bo o ni àṣírí, ti yoo si ṣe amojukuro fun un, tabi ki O fi ìyà jẹ ẹ lori ẹ, Mo ti fi ori jin in. Lẹ́yìn naa ni o tun tun ẹṣẹ da, o wa sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fi ori ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun wa sọ pé: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o wa mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti yoo waa bo o ni àṣírí, ti yoo si ṣe amojukuro fun un, tabi ki O fi ìyà jẹ ẹ lori ẹ, Mo ti fi ori jin ẹrú Mi. Lẹ́yìn naa ni o tun tun ẹṣẹ da, o wa sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fi ori ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun wa sọ pé: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o wa mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti yoo waa bo o ni àṣírí, ti yoo si ṣe amojukuro fun un, tabi ki O fi ìyà jẹ ẹ lori ẹ, Mo ti fi ori jin ẹrú Mi. Ki o maa ṣe ohun ti o ba fẹ́ lópin ìgbà ti o ba jẹ pe ti o ba ti n da ẹṣẹ naa ni yoo maa fi ẹṣẹ naa sílẹ̀, ti yoo si ká abamọ, ti yoo si pinnu pé oun ko nii pada síbẹ̀ mọ, ṣùgbọ́n ẹ̀mí rẹ maa borí rẹ, yoo tun wa da ẹṣẹ naa padà, lópin ìgbà ti o ba n ṣe báyìí, ti o n da ẹṣẹ, ti o si n ronupiwada, maa fi ori jin in; torí pé ìrònúpìwàdà maa n wó ohun ti o ba ṣáájú rẹ ni.