- Ọla ti n bẹ fun Isilaamu ati titobi rẹ, ati pe dajudaju o maa n bi awọn ẹṣẹ ti o ṣaaju rẹ wo.
- Gbigbaaye ikẹ Ọlọhun pẹlu awọn ẹru Rẹ ati aforijin Rẹ ati amojukuro Rẹ.
- Ṣiṣe mimu orogun mọ Ọlọhun ni eewọ, ati ṣiṣe pipa ẹmi ni ọna ailetọọ ni eewọ, ati ṣiṣe agbere ni eewọ, ati ṣiṣe adehun iya fun ẹni ti o ba ṣe awọn ẹṣẹ wọnyii.
- Ironupiwada ododo ti o so papọ mọ imọkanga ati iṣẹ daadaa maa n pa gbogbo ẹṣẹ nla rẹ titi dori iṣe keferi si Ọlọhun ti ọla Rẹ ga.
- Ṣiṣe ijakan ati kiko irẹwẹsi nibi ikẹ Ọlọhun ti mimọ n bẹ fun Un ni eewọ.