- Àkólékàn awọn Sọhaba- ki iyọnu Ọlọhun maa ba wọn- ati ipaya wọn ninu nnkan ti o n bẹ fun wọn ninu awọn iṣẹ ti wọn ṣe ni asiko aimọkan.
- Isẹnilojukokoro lori iduroṣinṣin lori Isilaamu.
- Ọla ti o n bẹ fun wiwọ inu Isilaamu ati pe dajudaju o maa n pa awọn iṣẹ ìṣáájú rẹ́ ni.
- Ẹni ti ko ṣe Isilaamu mọ ati ṣọbẹ- ṣelu, wọn yoo ṣe ìṣirò gbogbo iṣẹ́ kọọkan fun un eyi ti o ṣáájú ni asiko aimọkan, ati gbogbo ẹṣẹ kọọkan ti o ṣe ninu Isilaamu.