- O di dandan fun onilaakaye ki o tètè yara ronupiwada, ki o si ma fi aya balẹ nibi ète Ọlọhun ti o ba ṣi wa lori àbòsí.
- Bi Ọlọhun ṣe n lọ àwọn alabosi lara ti ko tete fi iya jẹ wọn lati dẹ wọn lẹ́kẹ ni ati lati ṣe adipele iya wọn ti wọn ko ba ronupiwada.
- Abosi wa ninu awọn okùnfà ìyà Ọlọhun fun awọn èèyàn.
- Ti Ọlọhun ba pa abúlé kan run, àwọn ẹni rere le wa ninu ẹ, àwọn wọ̀nyí wọn maa gbe wọn dide ni Ọjọ́ Àjíǹde lori nǹkan ti wọn ku le lori ninu daadaa, ki iya naa o ko wọn sinu ko ni wọn lara.