- Jijẹ sunnah sisalamọ lori bi hadīth naa ṣe gbe e wa, ti ẹni ti o n rin ba salamọ si ẹni ti o n gun nkan ati eyiti o yatọ si ìyẹn ninu nkan ti wọn sọ yẹn, o lẹtọọ, sugbọn ìyẹn yapa si eyi ti o fi n lọla julọ.
- Titan salamọ ka lori ọna ti o gba wa ninu hadīth naa ninu awọn okunfa ifẹ ati asopọ lo wa.
- Ti wọn ba ṣe deedee ara wọn ti wọn ba ara wọn dọgba nibi nkan ti wọn darukọ yẹn, nigba naa ẹni ti o loore julọ ninu wọn ni ẹni ti o ba kọkọ salamọ.
- Pipe ofin yii nibi ṣiṣe alaye gbogbo nkan ti ọmọniyan bukaata si.
- Ikọni ni awọn ẹkọ Isilaamu ati fifun oni iwọ ni iwọ rẹ.